Iwo, Omo mi owon,

O le ma mo mi;
sugbon, mo mo ohun gbogbo nipa re

Emi mo gbogbo bi o se njoko ti o si ndide

Ko si ohun kan nipa re ti o s'okunkun si mi

Emi mo iye irun ti o wa l'ori re

Ni aworan ara mi ni a da o

Ninu mi ni o ngbe, ni o nrin, ti o si nni iye

Lati inu mi ni o ti jade wa

Ki a to bi o ni mo ti mo o

Mo ti yan o ni ayo ki nto da ohun gbogbo

Igbesi aye re ko le je asise;
nitori wipe mo ti ko won si inu iwe mi

Emi ni mo se ipinnu asiko gere
eyi ti a bi o ati ibiti o ma a ma gbe

Iyanu gan ni eda re

Emi ni mo ran gbogbo isan re papo nigbati o wa l'oyun

Emi ni mo mu o jade kuro ninu oyun lojo ibi re

Opolopo ti ko mo mi ni won ti ba mi je l'oju aye

Emi ko jina; beeni nko si binu.
Pipe ni ife mi

Emi si nfe fi opolopo ife ba o lo

Eleyi ribe nitoriwipe omo mi ni iwo i se;
Emi si ni Baba re

Ebun ti Mo nfun o po ju iye
ti baba re ninu aye yi le fun o lo

Emi ni Baba t'O pe

Gbogbo ebun pipe ti onri gba,
lati owo mi ni o ti wa

Emi ni Olupese re ti yoo ba aini re pade l'otito

Eto mi fun o ni lati fun o ni ireti

Eleyi ri bee; nitori mo feran re pelu ife ayeraye

Ironu mi si o ju ti iyanrin eti okun lo

Emi a si maa yo lori re pelu orin kiko

Emi ki yo dawoduro lati maa se rere si o

Iwo ni eso mi

Emi nfe lati fi ese re mule pelu gbogbo okan ati aya mi

Mo si fe fi nkan iyanu han o

Ti o ba fi gbogbo okan re wa mi, iwo yoo ri mi

Fi gbogbo okan re fe mi,
Emi yoo si fun o ni ohun ti o nfe

Nitoriwipe Emi ni O sise ife ati ise sise ninu re

Emi le se ju nkan ti o l'ero re lo

Emi ni Eniti o le ti o l'ehin julo

Emi si ni Baba ti O ntu o ninu

Nigbati okan re ba baje, mo wa pelu re

Gegebi olusaguntan se ngbe awon
agutan re ni mo ngbe o mo'ra

Ojo nbo wa ti Emi yoo nu gbogbo omije re nu kuro

Emi yoo si mu gbogbo irora ti o ti ni ninu ile aye yi kuro

Emi ni Baba re;
ife kanna ti mo ni fun Jesu ni mo ni fun o

Ninu Jesu ni a ti fi ife mi han

Oun ni Alasepe ifihan bi mo se je ni gboogi

O wa lati fi han gbangba wipe Emi wa fun o;
Emi ki I se alatako re

Ati lati so fun o wipe Emi ki I ka ese si o l'orun

Jesu ku lati se ise ilaja larin iwo ati Emi

Iku Re je alasepe ifihan ife mi si o

Mo fi ohun gbogbo sile lati ri ife re

Ti o ba gba ebun ife ti Jesu, Omo mi,
o fihan wipe o ti gba mi niyen

Ko si si ohun kan ti o le ya iwo ati fe mi nipa.

Pada wa s'ile ki ajoyo ti o larinrin le bere ni ajule orun

Baba ni mo je; titi ayeraye,
Baba na a si ni Emi yoo ma a je

Ibeere ti mo ni fun o ni wipe,
nje iwo ha setan lati di omo mi?

Nje, Mo nduro de o o

Ife mi wa fun o, Emi ni Baba re,
Olorun Olodumare